Podcast: Effect of longer-term modest salt reduction on blood pressure - Yoruba language

DACHISee summary of the reviewDACHISee full review on the Cochrane LibraryDACHIListen to more podcasts

Ẹjẹ riru wọpọ ni orile ede Nigeria. Iwadi fi han wipe iyọ ajẹ ju jẹ ọkan ninu awọn idi ti oun fa ‘ẹjẹ riru’ laarin awọn agbalagba. Ifilọ yi wa lati jẹ ki olukuluku mọ pe din din iyọ jijẹ ku le din ‘ẹjẹ riru’ ku.

Ilana ajọ eto ilera ni Ọpọlọpọ Orilẹ ede ni lati mun àdínkù ba iyọ ĵiĵẹ.  Àkójopò iwadi  ti a ṣe jẹ ki o di mím pe adinku iyọ jíjẹ maa n jẹ ki ‘ẹjẹ riru’ dinku yálà laarin àwọn ti nṣe aisan ẹjẹ riru tabi eni ti ko ni arun yi rara.

Bi a ṣe n din iyọ jij ku, yio munki ẹjẹ riru' dinku, yoo si mu ilosiwaju ba ilera gbogbo eniyan; yala laarin awon aláwò funfun, aláwò dudu, okunrin ati obinrin. Siwaju si, èsì iwadi fi ye wa pe,  din din iyọ jijẹ ku si òṣuwòn fun igba pipe ko ṣe ìpalára fun ilera wa. Iwadi yi ṣe  átìleyìn to gbókun fun dindin iyọ jíjẹ ku laarin awujo, eleyi  ṣeé ṣe ki  o mun adinku ba aisan arun okan, arun rọpa rose ati bẹẹ bẹẹ lo. Siwaju si, iwadi wa ṣàfihan lọpọlọpọ igba pe  bi a ba  ṣe nṣe  adinku  iyọ jij si  ni ‘ẹjẹ  riru’ ndiku  si. Ni akotan, o se Pataki ki a din iyọ jijẹ ku ninu onjẹ wa, ki a baa le yẹra fun aisan ‘ẹjẹ riru’ ati awọn  aisan miran tí ó fojú joó.

Citation of Review: He FJ, Li JMacGregor GAEffect of longer-term modest salt reduction on blood pressureCochrane Database of Systematic Reviews 2013, Issue 4. Art. No.: CD004937. DOI: 10.1002/14651858.CD004937.pub2.