Ikede yi wa lati Ile Iyawe Cochrane ti o wa fun Eri Tuntun ti oda lori Ipinu ilera.
Arun HIV je isoro nla ni orile ede nigeria, eyi ti o nba omode ati agbalagba oniruru ojo ori ja. Opolopo awon omode ti o ni arun yi ni o ko o lati ara iya won, yala lati inu oyun, nigba irobi tabi ni igba omun mimu. Igbekale yi wa lati je ki o di mimo fun awujo wa wipe awon oogun ti o n’din arun HIV ku n’se ranwo lati dena itankale arun HIV lati ara iya si omo ninu oyun ati ni igba irobi.
Ni ipari odun 2009, egberun lona egberun meji abo awon omode ti ojo ori won ko i tii ju odun marundilogun ni won n’gbe igbe aye pelu arun HIV. Pupo ninu awon omo yii ni won ko arun yii ninu oyun, ni igba irobi iya won tabi nigba ti won si nmu omun. Eyi ni awon onimo ijinle alawo pe ni “itankale arun lati ara iya si omo”. Agbeyewo yii je ki o di mimo fun wa wipe, oogun ti o n’ din arun HIV ku, lee din itankale arun HIV lati ara iya si omo ku, ti awon iya ba lo oogun na ni igba oyun ati nigba ti won ba n fun omo l’omun. Koko agbeyewo yii ni lati je ki a mo iru oogun ti o ni agbara fun dindin itankale arun HIV lati ara iya si omo ku lai mu jamba lowo.
Ogooro awon onise iwadi ti se afiwe oniruuru laarin lilo orisirisi oogun ti o n’din arun HIV ku ati ailo oogun rara. Won tile tun se afiwe laarin lilo oogun ti o n’din arun HIV ku fun ojo pipe ati lilo oogun ti o n’din arun HIV ku fun igba kukuru. Abajade ise iwadi yii fihan wipe lilo oogun ti o n’din arun HIV ku fun igba kukuru lagbara lati dena itankale arun yii lati ara - iya -si - omo lai fa ewu kankan lesekese. O se pataki fun gbogbo awon alaboyun lati se ayewo arun HIV ki won ba a le mo ipo ilera ti won wa. Eleyi yoo je ki won se iranwo fun arawon, ki won o sii daabo bo omo ikoko ti won bi lowo arun HIV.
Ipolongo ati ogbufo si ede yoruba yii wa lati owo Cochrane Nigeria.
DACHI | DACHI |
Citation of Review: Siegfried N, van der Merwe L, Brocklehurst P, Sint TT. Antiretrovirals for reducing the risk of mother‐to‐child transmission of HIV infection. Cochrane Database of Systematic Reviews 2011, Issue 7. Art. No.: CD003510. DOI: 10.1002/14651858.CD003510.pub3.
Translator: Funmilayo Adie