DACHI | See summary of the review | DACHI | See full review on the Cochrane Library | DACHI | Listen to more podcasts | |
Ẹjẹ riru wọpọ ni orile ede Nigeria. Iwadi fi han wipe iyọ ajẹ ju jẹ ọkan ninu awọn idi ti oun fa ‘ẹjẹ riru’ laarin awọn agbalagba. Ifilọ yi wa lati jẹ ki olukuluku mọ pe din din iyọ jijẹ ku le din ‘ẹjẹ riru’ ku. Ilana ajọ eto ilera ni Ọpọlọpọ Orilẹ ede ni lati mun àdínkù ba iyọ ĵiĵẹ. Àkójopò iwadi ti a ṣe jẹ ki o di mímὸ pe adinku iyọ jíjẹ maa n jẹ ki ‘ẹjẹ riru’ dinku yálà laarin àwọn ti nṣe aisan ẹjẹ riru tabi eni ti ko ni arun yi rara. Bi a ṣe n din iyọ jijḙ ku, yio munki ẹjẹ riru' dinku, yoo si mu ilosiwaju ba ilera gbogbo eniyan; yala laarin awon aláwò funfun, aláwò dudu, okunrin ati obinrin. Siwaju si, èsì iwadi fi ye wa pe, din din iyọ jijẹ ku si òṣuwòn fun igba pipe ko ṣe ìpalára fun ilera wa. Iwadi yi ṣe átìleyìn to gbókun fun dindin iyọ jíjẹ ku laarin awujo, eleyi ṣeé ṣe ki o mun adinku ba aisan arun okan, arun rọpa rose ati bẹẹ bẹẹ lo. Siwaju si, iwadi wa ṣàfihan lọpọlọpọ igba pe bi a ba ṣe nṣe adinku iyọ jijḙ si ni ‘ẹjẹ riru’ ndiku si. Ni akotan, o se Pataki ki a din iyọ jijẹ ku ninu onjẹ wa, ki a baa le yẹra fun aisan ‘ẹjẹ riru’ ati awọn aisan miran tí ó fojú joó. |
Citation of Review: He FJ, Li J, MacGregor GA. Effect of longer-term modest salt reduction on blood pressure. Cochrane Database of Systematic Reviews 2013, Issue 4. Art. No.: CD004937. DOI: 10.1002/14651858.CD004937.pub2.